Oodua words for today
Today's Oodua words Read the full article
seen from Netherlands
seen from China
seen from Belgium
seen from China
seen from China
seen from China

seen from Türkiye
seen from Japan

seen from Singapore
seen from China
seen from United States
seen from China

seen from Russia
seen from China
seen from China

seen from Malaysia

seen from Netherlands

seen from Brazil

seen from Netherlands
seen from Netherlands
Oodua words for today
Today's Oodua words Read the full article
Èsì àyẹ̀wò tuntun Nàìjíríà fihàn pé “313” èèyàn ti gbàlejò Kofi 19 …àjọ NCDC
Èsì àyẹ̀wò tuntun Nàìjíríà fihàn pé “313” èèyàn ti gbàlejò Kofi 19 …àjọ NCDC À fi kí á bẹ Ọlọ́run kó bá wa dásí ọ̀rọ̀ àjàkálẹ̀ àrùn ajániláyà pàtì yìí, bí àwọn tó ní kòrónáfairọ̀ọ̀sì ní Nàìjíríà ti ń peléke sí i báyìí,lẹ́yìn tí àjọ NCDC tún kéde okòólélọ́ọ̀dúnrún dín méje èèyàn tí èsì àyẹ̀wò wọn sẹ̀sẹ̀ jáde. Ní báyìí, èèyàn ẹgbẹ̀rún méje, àti . òjìlélẹ́gbẹ̀rin dínkan (7839) ni àkọsílẹ̀ wà pé ó ti ní àrùn náà ní Nàìjíríà. Àkójọpọ̀ àwọn ìpínlẹ̀ tí èsì tuntun náà ti wá nìyí. Àjọ tó ń mójútó àjàkálẹ̀ arun l’órílẹ̀èdè Nàìjíríà, NCDC, kéde pé ènìyàn igba àti márùndínláádọ́rin ni àyẹ̀wò fihàn pé ó tún ní àrùn ni apinni léèmí Kòrónáfairọ̀ọ̀sì Naijiria. Nínú èsì àyẹ̀wò náà, ìpínlẹ̀ Èkó ní èèyàn mẹ́taleláàdóje, Ọ̀yọ́ ní mẹtàlélọ́gbọ̀n, Edo sì ní méjìdínlọ́gọbn. àwọn tó ti ní l’órílẹ̀èdè Nàìjíríà jẹ́ ẹgbẹ̀rún méje, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta lé mẹ́rìndinlọ́ggbọ̀n (7526). Ẹgbẹ̀rún méjì àti mẹ́rìnléláàdọ́sàn (2174), ti rí ìwòsàn, okòólérúgba lé kan (221) sì ti kú. Fẹ́mi Akínṣọlá Read the full article
Òòlù ìdájọ́ ré bá Fúnkẹ́ Akíndélé àti ọkọ rẹ̀ lẹ́yìn, owó ìtánràn, ìgbélé tipátipá, iṣẹ́ ìsìnlú bíi bọ̀kílẹ̀ àfojúdi .
Kò sí n tó burú kí abẹ òfin ba Ògbó Awo tó bá ń se bí ọ̀gbẹ̀rì . Ilé ẹjọ́ ti dá gbajúgbajà òṣèré sinimá, Fúnkẹ́ Akíndélé àti ọkọ rẹ̀ Abdulrasheed Bello lẹ́jọ́ pé ó jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án pé ó lòdì sí òfin kónílégbélé tí ìjọba Ìpínlẹ̀ Èkó gbé kalẹ̀ lórí dídẹ́kun àjàkálẹ̀ àrùn Coronavirus nípìńlẹ̀ Èkó àti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ilé ẹjọ́ rán àwọn méjéèjì lọ sí iṣẹ́ ìsìnlú fún wákàtí mẹ́ta lóòjọ́ fún ọjọ́ mẹ́rìnlà, yàtọ sí ọjọ́ Sátidé àti Àìkú. Bákan náà ni iléẹjọ́ ní kí wọ́n san owó ìtanràn ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn náírà. Bákan náà ni ìdájọ́ ọ̀hún tún ní kí ọ̀kọ̀ọ̀kan lọ́kọláyà náà yóó lọ sí ibùdó pàtàkì mẹ́wàá ní ìpínlẹ̀ Èkó láti ṣe ìdánilẹ́kọ́ọ̀ àti ìlanilọ́yẹ lórí ìjìyà tó wà fún ẹni tó bá ṣoríkunkun sí òfin kónílé ó gbélé. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbọdọ̀ fi orúkọ àti nọńbà ìbánisọ̀rọ̀ gbogbo àwọn tó kópa níbi àjọyọ̀ náà. Bákan náà nìròyìn míì ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, Azeez Fashola tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Naira Marley tí àwọn agbófinró tí kọ́kọ́ kéde ṣaájú pé àwọn ń wá ló tí fúnra rẹ farahàn báyìí ní àgọ́ Ọlọ́pàá. Ìròyìn ń bọ lórí rẹ̀ láìpẹ́ ẹ fojú sọ́nà Òòlù ìdájọ́ ré bá Fúnkẹ́ Akíndélé àti ọkọ rẹ̀ lẹ́yìn, owó ìtánràn, ìgbélé tipátipá, iṣẹ́ ìsìnlú bíi bọ̀kílẹ̀ àfojúdi . Fẹ́mi Akínṣọlá Read the full article
Oodua Fantasy: Creatures from The Forest of No Return:
Kurekure (Ghomid) observing a (Yinmiyinmi) Dung Beetle Adeboye Adegbenro Read the full article
Àwọn obìnrin tọ́kasí pàtàkì ìbáraẹnidọ́gba láárin ọmọnìyàn
Àwọn obìnrin tọ́kasí pàtàkì ìbáraẹnidọ́gba láárin ọmọnìyàn Ọjọ́ kẹjọ ọdọọdún ni àyájọ́ àwọn obìnrin lágbàáyé níbi tí gbogbo àgbáyé tí ń kọjú sí àwọn obìnrin láti yòǹbó àwọn iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n gbé ṣe láì nọ́ọ́ní onírúurú ìpèníjà, ẹ̀dùn ọkàn àti Ìlàkàkà wọn fún àṣeyọrí gbogbo Ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin pẹ̀lú ìdọ́gba pẹ̀láwọn ọkùnrin ló gbòde gẹ́gẹ́ bíi ohun òjútáyé lásìkò àjọyọ̀ àyájọ́ obìnrin lágbàáyé ti ọdún yìí. Àkọmọ̀nà àyájọ́ náà fún ọdún yìí ni “ajàfẹ́tọ̀ ìbáradọ́gba ni mí: mímú ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin ṣẹ.” Nínú ọ̀rọ̀ tiwọn, àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé rọ àwọn èèyàn gbogbo láti jí gìrì gbógun ti àwọn ìpèníjà sísọ àìdọ́gba láàrin ẹ̀yà ẹ̀dá gbogbo. Nínú ọkàn ò jọ̀kan ọ̀rọ̀ tí wọ́n ṣọ ní ìrántí àyájọ́ yìí, àwọn obìnrin ní oríṣìríìṣí Ìlànà iṣẹ́ ajé gbogbo sọ̀rọ̀ lórí ìpèníjà tí wọ́n ń dojúkọ; paàpá jùlọ láàrin àwọn ọkùnrin lẹ́nu iṣẹ́ ajé gbogbo léyìí tí ò jẹ́ adínàgboòkú. Fẹ́mi Akínṣọlá Read the full article
Omijé bọ́ lójú ù mi nígbà tí mo rí olóògbé Pa Kasumu gbẹ̀yìn.—Olóyè Lere Pàímọ́
Omijé bọ́ lójú ù mi nígbà tí mo rí olóògbé Pa Kasumu gbẹ̀yìn.—Olóyè Lere Pàímọ́ Bá a pẹ́ tí tí, bí ẹni rebi,bi èmi sì gùn gùn gùn bí okùn tó gùn,ikú lòpin èèyàn. Ìjọ aláyé ti dáyé, lakásọlérí ti í ṣunkún ara a wọn, kò ṣẹ́ni tí ò níí kú, kò ṣẹ́ni tí oko baba rẹ̀ kò ní dìgbòrò. Ìlúmọ̀ọ́ká àgbà ọ̀jẹ̀ nídìí iṣẹ́ tíátà, Lere Paimọ ti sàlàyé pé lọ́pọ̀ ìgbà, àìrìríjẹ́, àìrímú tàbí ìrònú má a ń jẹ́ kí ọjọ́ ogbó dagun. Lásìkò tó ń bá akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lórí ikú tó pa àgbà ọ̀jẹ̀ nínú tíátà míràn, Pa Kasumu, Paimọ ní ó yẹ kí àgbàlagbà máa rí àánú gbà, láti ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn àwùjọ, kìí ṣepé èèyàn ń tọrọ. Àgbà ọ̀jẹ̀ nínú isẹ tíátà náà ní omijé bọ́ lójú òun nígbà t’óun rí olóògbé náà gbẹ̀yìn, nitori ipo to wa. Ó wá se àdúrà pé kí Aláwùràbí dí ẹbí tí olóògbé náà fi sílẹ̀ mú, kí Ọlọ́run forí jin òkú. Nínú ọ̀rọ̀ tí ẹ̀, Salami sàlàyé pé ènìyàn tó ṣe é mú yangàn ni Pa Kasumu nígbà ayé rẹ̀, o si tún jẹ́ ẹni tí ó máa ń tèlé òfin àti ìlànà iṣẹ́ rẹ. Ọga Bello tẹ̀síwájú pé “Ó bani níńú jẹ́ sùgbọ́n kò sí nǹkan tí a le ṣe sí àṣẹ Ọlọ́run. Saájú àsìkò yìí ni a ti ń sàfẹ́rí Pa Kasumu nítorí ó ti tó ọdún díẹ̀ sẹ́yìn tí kò ti lè darapọ̀ mọ́ wa mọ́ láti ìgbà tí ó ti ṣe àìsàn” “Àdúrà mi ni pé kí Ọlọ́run tẹ́ ẹ sí afẹ́fẹ́ rere, kí ó sì tu àwọn ẹbí olóògbé nínú” Toyin Adewale, Jaiye Kuti, Toyin Adegbola àti Yomi Fabiyi naa wà lára àwọn òṣère tí o ti ń ṣe elédè lẹ́yìn rẹ Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Fabiyi ní “Ẹni iyì àti ẹ̀yẹ ni Pa Kasumu tí mo sì ní ìfẹ́ rẹ̀ gídí, mò ń ṣelédè lẹ́yìn rẹ̀ fún iṣẹ́ ribiribi tó ṣe nínú iṣẹ́ tíátà.” Ní ti Toyin Adegbola, Ó ní “O dárọ Kayode Odumosu, kí Ọlọ́run dẹlẹ̀ fún, kí ó sì tẹ sí afẹ́fẹ́ rere. Foluke Daramola- Salako ló kéde ikú Pa Kasumu lórí àtẹjiṣẹ́ instagram rẹ, gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ, Kayode Odumosu kú ní ilé ìwòsàn kan ní Abeokuta lásìkò àisan ranpẹ. Fẹ́mi Akínṣọlá Read the full article
Ilé-ẹjọ́ fi mílíọ̀nù mẹ́wàá náírà fa APC létí
Ilé-ẹjọ́ fi mílíọ̀nù mẹ́wàá náírà fa APC létí Ejo ti ile-ejo giga to fi ikale si ilu Abuja da ni ojo ketala, osu yii ni egbe oselu APC ni awon ko fara mo. Eyi ko tii saba waye ri ni orileede yii, ki ile-ejo giga da ejo ki awon kan wa ni won ni lati tun se ayewo re. Ejo naa lo fagi le ibo to gbe David Lyon wole gege bi gomina ipinle Bayelsa labe egbe oselu APC. Awon egbe PDP ni won pejo pe iwe eri igbakeji gomina naa ko moyan lori rara. Won ni orisiirisii oruko lo wa lori iwe eri igbakeji gomina naa, iyen Seneto Biobarakuma Degi-Eremienyo. Ile ejo ni ki awon to ni ejo ko te awon lorun fa asise awon jade sugbon ko si agbejoro to le fa asise Kankan jade ninu ejo naa. Eyi mu ki ile-ejo giga naa fi milionu mewaa naira fa egbe APC leti. Ile-ejo ni ki won ma se je ki iru re waye mo. Láti ọwọ́ Yínká Àlàbí Read the full article
Akiyesi Pataki
Arákùnrin oníṣègùn oyinbo tó jẹ́ ọmọ bíbí Nigeria to wá n'ilu USA, fi ọrọ ìyànjú yí ranṣẹ fún anfaani ara wa. Jọ̀wọ́ ká, kí ó sì mú lo fún ìtọ́jú ara rẹ. Dr. A. Malgwi Ọna ti àwọn ọdọ wá lóde òní, ngba ni àìsàn kidirin jẹ ohun tó ndẹru báni. Mo nfi itẹjade yí ranṣẹ torí kò le ràn wá lọ́wọ́ nínú ewu àìsàn kidirin. Jọ̀wọ́ fara balẹ láti ka ọ̀rọ̀ ìsàlẹ̀ yí: AKIYESI PATAKI KIDIRIN WA GBA ÀMÓJÚTÓ TÓ PÉYE Bí ọjọ́ méjì sí ìgbà tá wá yí, ní a gbọ ìròhìn ikú ọkàn ni àwọn òṣeré ori itage ọmọ ilẹ̀ wá ti àìsàn kidirin ṣekú pá. Bakanna, Minister alabojuto Iṣẹ́, Honourable Teko Lake wá nílé ìwòsàn ni ẹsẹ kan ayé, ẹsẹ kan ọrùn, nítorí àìsàn kidirin yí na ni. Idanilẹkọ yi dá lórí bí a ṣe lè toju ara wa ti ao ni bá wọn nipin ninu àìsàn kidirin yí. EYI NI ONA MẸ́FÀ PATAKI TI ÀÌSÀN KIDIRIN FI ŃṢE ENIYAN Dídá itọ mọ àpò itọ fún ìgbà pipẹ lai tọ, jẹ́ ọ̀nà àkọ́kọ́ tí ó má ń fà àìsàn kidirin. Tí ile itọ wá bá ń kùn ju bó ṣe yẹ lọ, o má nba ilé itọ wá jẹ́. Itọ yí tí ao tọ jáde nílé itọ wá, kún fún ọpọlọpọ kòkòrò aifoju ri ti a n pe ni bacteria, ti wọn ba npẹ ju nílé itọ wá, wọ́n má npọ sì ni kíákíá. Èyí má fún àwọn kokoro yí lanfani láti máa padà sínu kidirin wá àti àwọn ọ̀nà miran ti wọn lé gba jáde, eyi má ńṣe jamba fún kidirin wá púpò. Nígbà miran, àwọn kòkòrò yí ni ó má nfa aisan atọsi ọlọyun àti orisirisi àwọn aisan bí nephritis àti uremia. Tí itọ bá gbọn wá, kí a tọ itọ yí lásìkò tó yẹ.Jíjẹ iyọ pupọ ju, tún jẹ́ ọna miran ti àìsàn kidirin fi ń mú wá. Ao gbudọ jẹ́ iyọ ju ìwọ̀n 5.8 grams lọ ní ijoko ẹkan ṣoṣo.Jijẹ ẹran pupọ ju. Èròjà protein to wá nínú ẹran, to ba pọ ju má npa kidirin wá lára. Kí èròjà protein ṣe ń kuro lára ẹran tí a ń jẹ, bẹ ní kemika ammonia na ma ń jáde pẹlu rẹ. Kemika ammonia yí ko ni ìwúlò kankan lára. Tí ammonia yí bá ti ń poju bó ṣe yẹ lọ, ó má ńṣe àkóbá fún kidirin wá. Jíjẹ ẹran pupọ ju má njẹ ki ammonia yí po jù nínú kidirin wá ti yio ba kidirin wá jẹ́.Mímú kafini pupọ ju. Kafini jẹ́ lára àwọn èròjà tí ó má nwa nínú àwọn minira bí Coca-Cola, nescafe tea àti òbí tí a njẹ. Kafini má njẹ ki ifunpa wá (blood pressure) ga ju bó ṣe yẹ lọ. Tí ifunpa wá bá nga ju, ó má ń ṣàkóbá fún kidirin wá. Torinaa, ẹ jẹ ki a sá fún mímú minira bí coke ati mimu nescafe pupọ ju àti jíjẹ òbí pupọ ju.Áìmu omi dada. Kidirin wá nílò omi láti ṣíṣe daradara, tí a kò bá mú omi daradara kidirin wá má ń ṣíṣe afipa ṣe àti wipe àwọn ìdọ̀tí (Toxins) tí kidirin wá yẹ kó sẹ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ wá, yio tun padà sára wá. Nítorí náà, ẹ jẹ ki a ma mu omi daradara, o kere ju kí a má mu omi pure water mefa lojumo. Ọ̀nà tó rọrùn láti mọ bóyá a ń mú omi to boti yẹ. Wò awọ itọ tó ń tọ bóyá ó pọn tàbí ó mọ bí omi. Tí ó bá pọn, ó kí mu omi tó. To ba mọ, ó nmu omi tó.Áìbìkítà láti ṣe ìtọ́jú aisan tó bá ńṣe wá lásìkò àti botiyẹ. Ẹ jẹ ki a ma tètè bójú tó àìsàn tó bá ńṣe wá lásìkò àti botiyẹ. Ẹ má ṣe ayẹwo ara wa nípa lílo àwọn ẸRỌ IFUNPA, ẸRỌ ITỌ SUGAR, ki a ma lọ rí dókítà wá lore kórè. Kí a má lo àwọn ogún wá nígbà tó yẹ. Ẹ jeki a rán ara wa lọ́wọ́. Ọlọ́run a ra wá lọ́wọ́ àti àwọn ẹbí wá lọwọ orisirisi àìsàn. Ẹ̀JẸ̀ KÍ A SA FUN ÀWỌN OGUN WỌNYI WỌ́N ŃṢE ÌPALÁRA FUN ARA WA, WON JE OGUN TÓ LEWU GIDI GAN-AN. *D-cold *Vicks Action-500 *Actified *Coldarin *Cosome *Nice *Nimulid *Cetrizet-D Àwọn ogún yí ni èròjà Phenyle Propanol-Amide PPA. Èyí má nfa àìsàn rọparọsẹ(STROKE). Àwọn ogún yí ni ìjọba USA kò gbà láyé nilẹ wọn. Jọ̀wọ́, kí ó tó pá ìtẹ́ jáde yí rẹ, rán ọrẹ rẹ lọwọ nípa fífi ìtẹ́ jáde yí ranṣẹ si. Nípa ṣíṣe bayi, ó lè ràn ẹnikan lọwọ. Fi ranṣẹ sì ọpọlọpọ ènìyàn.. Àwọn dókítà ni ilu United States tí ṣe àwárí àìsàn jẹjẹrẹ kan tó ndamu ọmọ ènìyàn lamu, ohun tó ń ṣokùnfà àìsàn yì ni èròjà kan tí a npe ni Silver Nitro Oxide. Silver Nitro Oxide ni kemika tí wọ́n fi bo nọmba tó wà lára Recharge card, tí a bá ra recharge card, e ma fi ekana ha kemika yí tí ó lè fà àrùn jẹjẹrẹ yí. Ṣé alábàápín atẹjade yí pẹlu awọn olólùfẹ́ rẹ. ÌRÒHÌN ÌLERA TÓ ṢE PÀTÀKÌ Gba ìpè lórí fóònù rẹ sì etí osi.Má ma lo ogún òní horo pẹlu omi tutu.Má ma jẹ onjẹ to wúwo lẹhin ago marun irọlẹ.Mú omi daradara lowurọ, mú omi niwonba lalẹ.Àkókò to dára jù fún orun sísun ju ni àgó mẹwa alẹ sì àgó mẹrin arọ.Ó kò gbọ́dọ̀ sún ni kété tí ó bá lo ogún tàbí jẹun tán.Tí agbára batiri fóònù rẹ bá ti kú ìlà kan, ó kó gbọ́dọ̀ gba ìpè, torí wipe, àwọn agbára aifoju tí fóònù rẹ má nto ìlọ́po 1000 tí ole ṣe àkóbá fún ìlera rẹ. Ǹjẹ́ ole fi ite jáde yí ranṣẹ sì àwọn ènìyàn tí ó bìkítà fún? Èmi ti ṣe bẹ. Anu ṣíṣe ó nan wa lowo ṣùgbọ́n imọ jẹ agbára. Read the full article